GOMINA SANWO -OLU YAN AWỌN AKÒWÉ ÀGBÀ TUNTUN L’EKA ÈTÒ ÌLERA
Gómìnà Babajide Olusola Sanwó-Olu yan Akòwé àgbà méje miiran L’eka ètò ìlera Ìjọba Ìpínlè Èkó. Atejade kan tí Olórí Àwọn oṣiṣẹ Ọba Ìpínlè Èkó
Ògbéni Hakeem Muri-Okunola f’owo sí, ṣàlàyé pé, oṣiṣẹ ètò ìlera l’awọn ẹni tí wọn Yàn s’ipo náà latari ọwọ okunkundun tí wọn fi mú iṣẹ wọn àti pé wọn pegede l’asiko ayẹwo fínífíní tí wọn ṣe fún wọn l’osu Kẹrin, Ọdún 2022.
Ogbeni Muri-Okunola to orúkọ àwọn Akòwé àgbà náà l’ẹsẹ ẹsẹ, Dokita, Arabinrin Mabogunje Cecilia Abímbólá akosemose onipo kínní, L’ajo to n mojuto Òrò eto Ìlera, Dokita Arabinrin Bankole Olufunmilayo Olabisi, Akosemose oní pò Kejì, Ilé -Ise Ètò Ìlera, Dokita Arabinrin Zamba Olutoyin Emmanuela Ọga Àgbà Àjọ to n mojuto isakoso ètò ìlera, Dokita Bowale Abímbólá, Ọga Àgbà Ètò Ìlera, Àjọ Ètò Ìlera, Dokita Arabinrin Lajide Oludayo Ibidunni , Ọga tó n mojuto Òrò ilera eyin, N’ile iṣẹ ètò ìlera, Dokita Asiyanbi Oladapo Olubanwo, Ọga tó n mojuto Òrò ilera Ilé Ìwòsàn Alabode, Dokita Arabinrin Adeleke Monsurat , Oludari Àjọ to n mojuto Òrò didẹkun Ààrùn kòkòrò kò Gboogun N’ipinle Èkó.
Iyansipo náà bẹrẹ lati ọjọ kẹwàá, oṣù keje, ọdún 2023, Olórí àwọn oṣiṣẹ Ọba Ìpínlè Èkó sọ pé, ọkàn òun balẹ pé àwọn oṣiṣẹ Ọba ti wón ṣẹṣẹ Yàn sípò náà yóò karamasiki ṣiṣẹ wọn dáadáa torí pé, wón kunju iwọn l’ẹnu iṣẹ wọn. Wọn yóò kéde ọjọ ti wón yóò búra fún wọn àti ibi ti won gbe won lọ bí o bá yá.O wá kí gbogbo wọn kú oríire kí wọn má ṣe kaare l’ẹnu iṣẹ wọn, kí wọn tunbo f’owo Okunkundun mú iṣẹ wọn.